MENU

Where the world comes to study the Bible

God's Plan of Salvation (Yoruba)

Eni naa ti o ba ni Omo ni iye ainipekun, eni naa ti ko ni Omo Olorun ko ni iye ainipekun

Ibi kika yi so fun wa wipe Olorun ti fun wa ni iye ainipekun ati wipe iye wa ninu Omo Re Jesu Kristi. Ibeere ti o farahan ni wipe bawo ni a se lee ni Omo Olorun?

ISORO ENIYAN

Iyapa kuro lodo Olorun

Isaiah 59:2 Sugbon aisedede nyin li o ya nyin kuro lodo Olorun nyin, ati ese nyin li o pa oju re mo kuro lodo nyin, ti on ki yio fi gbo adura nyin.
Romu 5:8 Sugbon Olorun fi ife On papa si wa han ni eyi, nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa.

Gegebi bii iwe Romu ori karun ese ikejo, Olorun fi ife Re han si wa nipa iku Omo Re. Kini idi ti Jesu se ni lati ku fun wa? Nitori iwe mimo so wipe gbogbo eniyan ni o je elese. Lati da “ese” je lati kuna . Bibeli so wipe “gbogbo eniyan lo sa ti se, ti nwon si ti kuna ogo Olorun” (Romu 3:23) Ni ona miran ewe, awon ese wa muwa yapa si Olorun ti o je pipe ninu iwa mimo (ododo ati idajo) ati wipe Olorun gbodo da eniyan elese lejo.


Habakkuku 1:13a Oju re mo ju eniti iwo ibi lo, iwo ko le wo iwa-ika.



ALAINILARI ISE WA

Iwe mimo ko wa wipe ko si iwa rere eniyan, ise ti eniyan, iwa omoluwabi, tabi ise isin kan ko le je ki aje itewogba lodo Olorun tabi mu ki enikeni de orun. Omoluwabi eniyan, elesin eniyan, ati eniti ko mo ati alaimo ni won wa ninu oko kan. Gbogbo won ni o kuna odod Olorun ti o pe. Lehin ti Aposteli Paulu ti soro lori, eniyan alaimo, omoluwabi eniyan elesin eniyan, ni Romu 1: 18-3:8, Aposteli Paulu jeki o di mimo wipe awon Ju ati awon ara Hellene ni nwon wa labe ese, wipe, “ko si eniti ise olododo, ko si enikan” (Romu 3:9-10). Afikun eyi ni awon ikede ese oro iwe mimo wonyi:


Efesu 2:8-9 Nitori ore-ofe li afi ti fi gba nyin la nipa igbagbo; ati eyini kise ti enyin tikarayin: ebun Olorun ni: 9 Ki iae nipa ise ki enikeni ma ba sogo.
Titu 3: 5-7 O gba wa la, Ki ise nipa ise ti awa se ninu ododo sugbon gegebi anu re li ogba wa la, nipa iwenumo atunbi ati isodi titun Emi Mimo 6 Ti o da siwa lori lopolopo nipase Jesu Kristi olugbala wa; 7 Nitori naa, Ki a le dawa lare nipa ore-ofere, ki a si le so wa di ajogun gege bi ireti iye ainipekun.
Romu 4: 1-5 Nje kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara,ri? 2 Nitori bi a bad a Abrahamu lare nipa ise, o ni ohun isogo; sugbon kiise niwaju Olorun. 3 Iwe-mimo ha ti wi? Abrahamu gba Olorun gbo, a si ti ka a si ododo fun u. 4 Nje fun eniti nsise a ko ka ere na si ore-ofe bikose si gbese. 5 Sugbon fun eniti ko sise, ti 0 si ngba eniti o nda enia buburu lare gbo, a ka igbagbo re si ododo.

Ko si iwa rere eniyan ti o lee dara bi ti Olorun. Olorun pe ninu ododo. Nitori eyi, Habakuku 1:13Olorun ko le ni idapo pelu enikekeni ti kop e ninu ododo. Ki a ba lee je itewogba lati odo Olorun, a gbodo dara bi ti Olorun gann. Niwaju Olorun, a wa ni ihooho, ainiagbara, ati alaini ireti ninu ara wa. Ko si iye iwa omoluwabi ti o lee muwa de orun tabi fun wa ni iye ayeraye. Ki wa ni ona abayo?


Idahun Olorun

Kii se wipe Olorun pe nipa mimo nikan (eni nipa ise ododo wa, a kole kunju osuwon mimo Re ) sugbon O pe nipa ife, okun fun oore-ofe ati aanu. Nitori ife ati oore-ofe Re, Ko fi wa sile laini ireti ati ona bayo.


Romu 5:8 Sugbon Olorun fi ife On papa si wa han ni eyipe, nigbati awa je elese, Kriti ku fun wa.

Eyi ni irohin ayo ti Bibeli-ise iranse ihinrere Eyi ni ise iranse ebun Omo Re eniti o di eniyan (Olorun ninu eniyan), eni ti o gbe igbe aye alailese, ti o si ku lori igi agbelebu tori ese wa, ti a si ji dide kuro ninu ipo oku ti o si fihan wipe Omo Olorun Ni ni tooto ati wipe On ni aropo fun wa.

Eniti a pinnu re lati je pelu agbara omo Olorun, gege bi Emi mimo, nipa ajinde kuro ninu oku, ani Jesu Kristi Oluwa wa.


Romu 4:25 Eniti a a fi tore ese wa , ti o si jinde kuro ninu oku.
II Korinti 5:21 Nitori o ti fi I se ese nitori wa, eniti ko mo esekese ri; ki awa le di ododo Olorunninu re.
Peteru 3:18 Nitori Kristi pelu jiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto, ki o1e mu wa de odo Olorun, eniti a pa ninu ara, sugbon ti a so di aaye ninu emi.


BAWO NI ASE LEE GBA OMO OLORUN?

Nitori ohun ti Jesu Kristi se fun wa lori agbelebu, Bibeli so wipe “Eniti o ba ni Omo ni iye.” A lee gba Omo, Jesu Kristi, gegebi Olugbala nipa igbagbo ti ara wa, nipa gbigbekele eniti Kristi i je ati iku Re fun awon ese wa.


Johannu 1:12 Sugbon iye awon ti o gba a, awon li o fi agbara fun lati di omo Olorun, ani awon na ti o gba oruko re gbo.
Johannu 3:16-18 Nitori OLorun fe araye tobe ge, ti o fi Omo bibi re kansoso funni, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun. 17 Nitori Olorun ko ran Omo re si aiye lati da araiye lejo; sugbon ki a le ti ipase re gba araiye la. 18 Eniti o gba a gbo, a ko ni da a lejo; sugbon a ti da eniti ko gba a gbo lejo na, nitoriti ko gba oruko Omo bibi kansoso ti Olorun gbo.

Eyi tumo si wipe eni kookan gbodo to Olorun wa ni ona kanan: (1) gege bi elese ti o mo ara ni elese., (2) mo wipe ko si ise eniyan ti o yori si igbala, ati (3) gbekele Kristi patapata nipa igbagbo nikan fun igbala wa.

Bi iwo setan lati gba ati gbekele Kristi gegebi Olugbala re, o lee fe fi igbagbo re han ninu adura kekere yi i ti o jewo ese re, ti o si ngba idarijin Re ati ti o nri igbagbo re sinu Kristi fun igbala re.

Bi o ba sese ni gbekele ninu Kristi, o nilo lati mo siwaju si I nipa igbe aiye re tuntun ati bi o se le rin pelu Oluwa. A da a laba wipe ki bere lati ma a keko ni adiresi yi ABCs for Christian Growth www.bible.org Awon eko wonyi yio mu ni sisentele ni eredi ati okodoro otito oro Olorun. Ewe, yio si ran o lowo lati ni ipile ti ni agbara fun igbagbo re ninu Kristi.


Nje o gba adura yi bi ?



Report Inappropriate Ad